Constitution of the Federal Republic of Nigeria

Chapter IV: Fundamental Rights
#Law2Go version: YORUBA

ABALA KETALELOGBON (33): ETO IGBE AYE ENI (Igbesi aye re je ti re)

  • Iwo ati gbogbo eda eniyan ti o wa nile aye loni eto lati gbe inu aye. O lodi si ofin lati pa eniyan.

 ABALA KERINLELOGBON (34): ETO SI IBOWO FUN’RA ENI (O leto lati je ki a ba o se pelu ibowo, bee si lo kii se eru enikeni).

  • gbodo bowo ati ola fun gbogbo eniyan ninu ajosepo re pelu won ya la, o feran won tabi beeko. Bakan naa la gbodo bu ola fun iwo naa.
  • lodi si ofin fun enikeni lati fi iya je o tabi lati se o bi eni pe o kii se eniyan.
  • tapa si ofin fun enikeni lati so e di eru tabi alagbase ni tipatipa tabi lati bawon se ise loranyan. Sugbon bi ile ejo ba paa lase fun o, tabi o pinnu lati darapo mo ileese ologun tabi olopa tabi o n sinru ilu gege bi agunbaniro ti o pon dandan(NYSC), won le ran o lati se awon ohun kan lai naani ife inu re.

ABALA KARUNDILOGOJI (35): ETO SI OMINIRA ARA ENI (O leto si ominira ara re)

  • leto si ominira ati iyonda ara re
  • Oun kan naa ti o le mu ki ominira ati iyonda re ni gbedeke ni ti ile ejo ba paa lase lati di won re latari pe o wu iwa odaran tabi o ko lati te le idajo ile ejo, tabi ti ojo Ori re wa labe odun mejidilogun (18 years), tabi o lugbadi arun ti o le ran eniyan ( bii Ebola), tabi o larun opolo, tabi o je ologun oloro tabi omuti lile, eyi le mu ki ijoba lase lori idiwon ominira re.
  • Ko da nigba ti o wu iwa odaran tabi won fesun kan kan o, ti o si n duro de igbejo, ko tona lati ti e mo atimole ju iye akoko isewon ti ile ejo da fun irufe esun oun lo.
  • (Fun apeere, labe ofin iwa odaran, ijiya fun jiji maaluu gbe ni ewon odun meji, fun idi eyi ti eni ti a fesun kan ba ti pari odun meji latimole laijepe won ti pari igbejo re, won gbodo tu sile lominira laise aniani kan kan mo.)
  • Ti owo sikun awon agbofinro ba te o tabi won ju o sahamo, o le yan lati ma so nkan kan tabi lati ma dahun ibeere eyi yowuu titi igba ti o ba to ri agbejero tabi eni yowuu ti okan re fe. Olopa tabi awon agbofinro ko le fi tipatipa mu o lati ko tabi lati so ohun kohun titi di igba ti o ti lanfaani lati ba eni yowuu ti o ba fe ba soro.
  • Ti olopa tabi agbofinro eyi keyi ba mu o tabi ti o mole, won gbodo so fun e idi ti won fi mu e tabi ti won fi ti e mole pelu alaye ninu akosile lede ti o gbo daada laarin wakati merinlelogun.
  • Ti esun ti won fi kan o ko ba to Idajo ewon iku gege bi ijiya ti o to, won ko gbodo mu e tabi ti o mole ju ojo kan lo laije pe won mu oju re ba ile ejo, ayafi ti ko ba si ile ejo ti o le gbo esun naa, nitosi ibuso ojogi. Ti o ba ri bee, won sile ti o mo ahamo, sugbon o pe tan, ojo meji tabi fun igba miran ti o wu etii gbo.
  • Ti won ba mu o tabi ti e mo ewon laito/laiba ofin mu, o leto si itanran gba mabinu tabi aforiji loju taye lati odo awon alase ti oro naa kan tabi agbofinro ti o mu o tabi ti e mole.

ABALA KERINDILOGOJI (36): ETO SI IDAJO ODODO (O leto lati je ki won gbo ti enu re)

  • leto lati so bi Oro/ isele naa se je/waye 
  • Orun re si mo, a fi igba ti won ba to fidi re mule pe o jebi.
  • Ti eni keni ba n fesun kan o pe o wu iwa odaran kan, ojuse ti won ni, (kiise ti re) lati fidi re mule pe iwo lo jebi. (A yafi ti o ba je esun ara oto ti ofin pon-on ni dan dan pe o gbodo fidi alaye mule.
  • Lasiko igbejo esun ti won fi kan o, o leto si ekunrere alaye lori irufe esun ti won fi kan o, won si gbodo so fun e pelu ede to ye o yekeyeke. Won gbodo fun o lakoko ti o to ati eroja ti o ma lo lati sagbekale awijare ti re, won si gbodo fun e laaye lati soniduro ara re tabi ki o gba agbejoro ti o wu e.
  • leto lati pe eleri kan lati jeri gbe o lese, bee si lo tun lominira lati beere ibeere lowo eleri ti o n jeri tako e.
  • Ti ede ti won fi n se igbejo ko ba ye o jowo jare je ki won mo. Ojuse won ni lati wa olugbifo kan ti yoo ran o lowo lati tumo re fun e lede ti o gbo ti o si ye o daada, laigba owo kan kan lowo re.
  • Ni ge le ti won ba ti gbe idajo kale, iwo tabi asoju re leto lati beere eda iwe idajo esun naa laarin ojo meje.
  • A ko gbodo da o lejo esun iwa odaran, ayafi ti ofin ba so bee ti ijiya re si tun wa lakosile ninu ofin.(awon esun ti o wa labe ofin ilu ati asa kii se iwa odaran labe ofin)

ABALA KETADILOGOJI (37): ETO SI IGBE AYE ARA ENI ATI IDILE ENI (O leto si aye re)

  • leto si aye re ti o fi mo ile re, ero ibanisoro re, iwe atejise ori ago re, iwe atejise ori ero ayelujara, ati bee bee lo. A gbodo daabo bo o ki idaniloju to peye si wa.

ABALA KEJIDILOGOJI (38): ETO SI OMINIRA EROGBA ARA ENI, IFE OKAN ATI ESIN (Gbe igbe aye re ninu ominira)

  • leto lati gbero nkan yowuu ti o ba wu o.
  • leto lati se ijosin ki o si se ise isin re funra re tabi pelu awon miran nipase ijosin ati ikoni. O tun lominira lati yi esin re pada ti o ba fe. Eni keni ko gbodo fi tipatipa mu o lati dara po mo esin ti re/won. Eni keni ko gbodo fi tipatipa mu o lati fi esin re sile. Beeni kiise oranyan lati ni esin kan. Ofin ko faaye gba o lati je omo egbe okunkun.

ABALA KOKANDILOGOJI (39): ETO SI OMINIRA LATI WI TI ENU RE ATI IWE IROYIN (Wi ti re)

  • leto lati ni ero ti re
  • leto lati so ti re
  • leto lati so ti enu re ki o si pin ero re pelu awon miran laisi idiwo kan kan.
  • leto lati se idasile ki o si ni ileese mohunmaworan, asoromagbesi, ko da iwe iroyin, ni kete ti o ba ti gba iwe ase lati odo ijoba.
  • leto lati sin, ki o si bojuto ikanni ayelujara yowuu ti o ba fe.
  • Kii se ti te eto yii loju ni, bi won ba se idasile ofin ti o ndena re lati ma fi iroyin asiri sita, tabi lati ma je ki o gbe awon iroyin kan sita nitori ise re gege bi osise ijoba, agbejoro, dokita tabi idajo ile ejo.

ABALA OGOJI (40): ETO SI IBASEPO/AKOJOPO ALAAFIA ATI EGBE (O leto lati lajosepo pelu awon min-in).

  • leto lati sakojopo ki o si darapo mo egbe lati daabo bo erongba re; tabi egbe olokoowo yowuu ti o ba wu o. O tun leto lati ma darapo mo egbe. O leto lati kuro ninu egbe nigba yowuu ti o ba fe.
  • leto lati da egbe oselu sile bee si lo le darapo mo egbe oselu ti o wu o, sugbon egbe oselu naa gbodo ti forukosile lodo ajo eleto idibo apapo(INEC)

ABALA KOKANLELOGOJI (41): ETO OMINIRA LATI RIN BI O SE WU NI (O leto lati rin bo se wu o)

  • Gbogbo omo orileede Naijiria lo leto lati rin yan fanda bo se wuu kaakiri orileede Naijiria.
  • Gbogbo omo orileede Naijiria lo leto lati gbe lagbegbe ti o ba wuu lorileede Naijiria. Ya la lekun ariwa tabi guusu, tabi ila-orun, ki baa se apa iwo-orun, o leto lati re irinajo lo ki o si gbe nibikibi lorileede yii.
  • Ni won ba igba ti o ba je Omo orileede Naijiria, ko si eni ti o le o kuro ni Naijiria tabi ma je ko rinrinajo kuro lorileede Naijiria; tabi di ona re lati wa si orileede Naijiria, ayafi ti o ba wu iwa odaran kan ni Naijiria ti o wa fe sa jade sa lo si orileede miran-an; tabi nibi ti Naijiria ati orileede min-in pe ti o ba wu iwa odaran kan lorileede won, o ko le farapamo ni Naijiria, orileede Naijiria yoo jowo re fun won fun igbejo esun tabi ijiya.

ABALA KEJILELOGOJI (42): ETO OMINIRA KURO LOWO IYAPA (O leto kan naa labe ofin gege bi elomiran)

  • Eni keni ko leto lati ya o s’oto si awon miran nitori pe o je omo ilu tabi eya tabi orisun ibi kan, obinrin tabi okunrin, esin tabi oye oselu tabi nitori isele ti o romo bi won se bi o.

ABALA KETALELOGOJI (43): ETO NI LATI NI DUKIA TI KO SE E GBE KAAKIRI NIBIKIBI LORILEEDE NAIJIRIA (O leto lati ra ile tabi dukia nibikibi lorileede Naijiria)

  • Gbogbo Omo Naijiria lo leto lati ni dukia nibikibi ni Naijiria. Hausa le ni ile si Onitsha, omo Igbo lobinrin le ni ile itaja nla si ilu Eko, Yoruba naa le da oko si Jigawa.

ABALA KERINLELOGOJI(44):  IPONDANDAN LATI NI DUKIA (O leto lati gba ebun gba ma binu) 

  • Fun idi yowuu ti ijoba ba fe gba ile re, won gbodo san gba mabinu fun o kiakia beesi lo leto lati gba ile ejo lo ti inu re ko ba dun sii.
  • Gbogbo eroja, nka alumoni; eroja epo robi ati afefe gaasi ti o wa labe  tabi lori ile orileede Naijiria tabi lori, tabi ninu omi ti o wa labe orileede Naijiria je ti ijoba apapo.

ABALA KARUNDILAADOTA (45): FI FI ONTE ATI IDIWON LE ETO OMONIYAN (Ijoba le fi onte idiwon le eto re lawon akoko kan)

  • Eto igbe aye ati idile eni(Abala ketadilogoji;37), eto ominira erongba, ife okan ati esin(Abala kejidilogoji; 38); eto ominira lati wi ti enu eni ati  iwe iroyin (Abala kokandilogoji; 39); eto lati da tabi darapo mo egbe yowuu (Abala ogoji; 40) ati eto ominira lati rin bo se wu ni(Abala kokanlelogoji;41) le ni gbedeke onte idiwon ofin ti a le fidi re mule fun anfaani igbe aabo, idaabo bo emi ati dukia, ase gbogbo gboo, igbe aye rere tabi igbe aye ilera gbogbo ilu; tabi fun ise pataki idaabo bo awon eto ati ominira awon elomiran.
  • Lasiko ilu ko fararo, (akoko ilu ko fararo ni igba ti Aare Orileede Naijiria ma nkede pe orileede Naijiria ko fararo latari ogun), eto si ominira ara eni (Abala karundilogoji; 35) o se e se ki ilana yii fenu so abala ofin ile igbimo asofin apapo ni onte gbedeke ni won fi gbodo bojuto ilu ko fararo. Ko si awawi tabi idena ti o le fi onte gbedeke si eto igbe aye eni (Abala ketalelogbon) ayafi lori isele iku ti o waye nipase ogun ji ja; ati eto Abala kerindilogoji (36); isori kejo(8) ti o n tako ifiyajeni fun esun ti kii se iwa odaran Lasiko ti a fi kan ni ati fi fi ijiya ti o lagbara ju lo je afura si eleyi ti ko si lasiko isele esun naa ni ayipada ko le ba lainaani isele oun.

ABALA KERINDILAADOTA(46); ETO IDAJO OTO NI ILE EJO GIGA ATI IRANWO ETO IDAJO (O leto idajo ododo)

  • Ti o ba ro pe eni keni ti ta pa si eto re lati abala ketalelogbon de abala kerindilaadota(Ori Kerin;Chapter IV) inu ofin yii tabi eni keni fe e fi eto re du e, gba ile ejo giga yowuu ti o ba sunmo e lo fun ona abayo.
  • Ile igbimo asofin apapo yoo pe se iranwo owo ti o ko ba ni owo ati agbara lati gba agbejoro.